HYMN 494

(FE 520) 
"Loruko Jesu a Nasareti dide" - Act.3:61. ONISEGUN nla wa nihin

   Jesu A-bani daro

   Oro re mu ni l‘ara ya

   A gbo ohun ti Jesu. 

Egbe: Iro didun I’orin Serafu 

      Oruko didan l'enu enia

      Orin ti o dun julo

      Ni Jesu! Jesu! Jesu!


2. Oruko Re le eru mi, 

   Oruko Jesu nikan

   B‘okan mi ti fe lati gbo

   Oruko Re ‘yebiye. 

Egbe: Iro didun...


3. Omode at’agbalagba 

   T'o fe oruko Jesu

   Le gba ipe ore-ofe 

   Lati sise fun Jesu.

Egbe: Iro didun...


4. Nigbat' a ba si de orun 

   Ti a ba si ri Jesu

   Ao korin y’ite Re ka

   Orin Oruko Jesu.

Egbe: Iro didun I’orin Serafu 

      Oruko didan l'enu enia

      Orin ti o dun julo

      Ni Jesu! Jesu! Jesu! Amin

English »

Update Hymn