HYMN 497

(FE 524) 
Tune: Oluwa Olorun gba wa1. EGBE Aladura mura

   Lati pade Kerubu
 
  Jesu lo pe nyin lo yan nyin 

  On lo d’Egbe yi sile

  O si pe gbogbo aiye

  Lati w’oko ‘gbala yi

  Jesu mu wa de ‘te ogo 

  B’ojo wa ti nkoja lo.

Egbe: Ojo nlo, Ojo nlo. 2ce

      Ise po t'awa yio se

      B’ ojo wa ti nkoja Io.


2. Egbe Serafu d’amure 

   Lati pade Kerubu

   E ma je k’amure nyin tu 

   Lati pade Kerubu

   Gbe ida ‘segun soke

   Iye s’Olorun Daniel 

   Alleluya Jesu mbo

   B’ojo wa ti nkoja lo 

Egbe: Ojo nlo, Ojo nlo...


3. Olorun Metalokan wa 

   Lati gbo adura mi 

   Jesu Olugbala mi wa 

   Lati gb’ebo ope mi 

   Emi Mimo sokale

   F’ore ofe ba wa gbe

   Ise po t’awa o se

   B‘ojo wa ti nkoja lo 

Egbe: Ojo nlo, Ojo nlo...


4. F'okan fe so gbogbo wa po 

   B'ojo wa ti nkoja lo

   Kokan la o fa won s'agbo wa, 

   B’ojo wa ti nkoja lo

   Sugbon ‘eso ti a gbin 

   L‘osan at‘oru yio hu 

   Gb’awon to subu dide

   B’ojo wa ti nkoja lo.
   
Egbe: Ojo nlo, Ojo nlo. 2ce

      Ise po t'awa yio se

      B’ ojo wa ti nkoja Io. Amin

English »

Update Hymn