HYMN 500

(FE 528) PM
“Nwon si fori bale fun Olorun ti o
joko lori ite, wipe Amin! 
Hallemyah” - Ifihan19:41. AWA l’egbe Kerubu Serafu

  T'Oluwa fun 'ra re gbe dide

  Awa f'ohun wa ke Alleluyah

  Si Olorun Awimayehun

  Aje kan ko to lati bori Egbe yi 

  Oso kan ko to lati bori Egbe yi 

  Oluwa fun ‘ra re ni Oluto wa,

  Awa Egbe Serafu ko je f’esu laye. 

Egbe: Eda Ie fe o, ki nwon korira

      Aiye Ie bu o, ki nwon sepe fun o 

      Bi nwon se ju yi lo nitori Jesu

      Ma wo be, ma wo be)

      Ma wo be, se 'fe Oluwa). 2ce


2. Ayo ni ki eyi je fun yin

   Enyin ti Lusifia ti te ba 

   Oluwa ran Egbe Mimo yi

   Lati fi ase gbe nyin dide

   E mase fi aigbagbo se ‘ra nyin lese 

   Eni nla ni Jesu Olori Egbe wa, 

   Nitorina ki e f’okan nyin bale

   K'e mo p’okunkun ko bori imole ri o. 

Egbe: Eda Ie fe o...


3. Bi Jesibel ba mo pe beni

   Yio ii f‘on niwaju Jehu 

   Ki ba le tiro k‘o gun gege

   Tun bere pe s'alafia ni

   Eni ns‘ ota Olorun t‘o nwa' lafia 

   Anfani kil' o wa ninu aje sise

   E tari re lokiti fun aja je

   Awa Egbe Kerubu ko ni f‘esu laye. 

Egbe: Eda Ie fe o...


4. Ka p‘arapo sise Oluwa 

   Ninu Egbe Mimo Kerubu 

   K’a mase ro p‘enikan kere 

   J‘eniti Oluwa le lo lo 

   Ranti Alufa Eli pelu Samuel

   Modikai pelu ayaba Esta 

   Meji pere yi t‘eko fun Serafu 

   Awa Egbe Seran ko ni f’esu laye. 

Egbe: Eda Ie fe o...


5. Ki gbogbo aiswaju Egbe 

   Mura sile de bibo Jesu

   Irohin won ki se kekere

   Niwaju ite Baba loke

   Asaju to de be to npitan ara re

   Ki Jesu to le mo pe asiwaju ni,

   Ki y'o wo ‘nu ogo na pel‘ Oluwa 

   Awa Egbe Serafu ko je f’esu laye. 

Egbe: Eda Ie fe o...


6. Gbogbo enyin aje at'oso

   T’o wa ndi se Oluwa lowo 

   T'Oluwa kilo fun nyin titi

   Ti e ko fe ronupiwada

   Ranti oruko t’a ko s‘egbe ogiri 

   Mene, Mene, Tekeli Peresini

   A ti won o wo, o fuye ju gba lo 

   Awa Egbe Serafu ko ni f’esu laye.

Egbe: Eda Ie fe o, ki nwon korira

      Aiye Ie bu o, ki nwon sepe fun o 

      Bi nwon se ju yi lo nitori Jesu

      Ma wo be, ma wo be)

      Ma wo be, se 'fe Oluwa). 2ce Amin

English »

Update Hymn