HYMN 501

(FE 529) 
Tune: Oluwa Olorun gba wa
“E ma foiya awon eniti npa ara"
- Matt. 10:281. OLORUN wa, awa mbe O 

   Sokale si arin wa

   Ran agbara ‘segun nla Re 

   S‘ori awon omo Re 

   F'ore ofe igbala

   Yi awa omo Re ka

   K‘a le ma yo n'nu ore Re

   K’a si le segun ota. 

Egbe: O d'ofo (4)
  
      Ajahula Sakula 

      Agbara aje d'ofo.


2. Enyin Angeli Olusegun 

   Sokale l’agbara Re

   E dide pel’ohun ija yin 

   Lati segun f’Egbe yi 

   Emi-Mimo daba orun 

   Fi ore isegun Re

   Yi awa omo Re ka

   K‘a le ma yo ‘nu segun. 

Egbe: O d'ofo...


3. Karubu oni ‘da ina 

   Sokale l'agbara Re 

   Maikel olori ogun wa 

   Sokale l‘agbara Re 

   Awa omo Re duro

   De agbara ina na

   T'o sakale sara won

   T‘o sote s'awon omo Re.

Egbe: O d'ofo...


4. Olorun Alagbara nla

   T‘o pa ara Egypt run

   T’o ri won sinu okun pupa 

   Ti nwon ko le dide mo 

   Sokale Eleda wa

   Doju ota wa bo le

   Ki nwon subu n’iwaju Re 

   Ki nwon si di ‘temole.

Egbe: O d'ofo...


5. E ma yo enyin enia mi 

   Ninu agbara nla mi

   E ho iho isegun nla

   Bi t’ awon omo Isreal 

   Maikel ti segun fun nyin 

   O si di nyin l’amure

   Te siwaju n’ipa agbara Re, 

   E ja k’e si le segun.

Egbe: O d'ofo...


6. Emi ni El El-Sahula 

   Oba Ajasegun ni mi 

   Emi ni Jehofa Hullam 

   Oba Awimayehun

   E ma yo ninu ore mi 

   K’e si ma dupe pelu 

   Emi ni Asaholah

   Oba a-fi-dip’o-te‐mole.

Egbe: O d'ofo (4)
  
      Ajahula Sakula 

      Agbara aje d'ofo. Amin

English »

Update Hymn