HYMN 502

Tune: Will your Anchor Holds?1. IWO ha ni idakoro t’o daju 

   Ninu irumi at’iji aye 

   Nigba ti ikun omi ba dide 

   Idakoro re ha le duro.

Egbe: ldakoro n be fun okan wa 

      B’o ti wu ki iji naa le to

      Jesu l’Apata ti ko le ye 

      Lor’Apata ife Re l'a n duro.


2. A ti gunle s’ebute isinmi

   Ko s’ewu a n be lowo Oluwa 

   Dakoro t’O ti s’inu okan mi 

   Yoo duro b’o ti wu k’iji le to.

Egbe: ldakoro n be fun okan wa...


3. Yoo duro sinsin b’eru tile de

   Awon ota wa ni oju yoo ti 

   Ko si igbi t‘o le ba wa l’eru 

   Awa n'idakoro t'o daju. 

Egbe: ldakoro n be fun okan wa...


4. Yoo duro girl titi de opin 

   Titi iku yoo ti p’oju wa de 

   Looro ajinde ko si Ie kuna 

   Oun n‘idakoro ireti wa.

Egbe: ldakoro n be fun okan wa...


5. ‘Gba t'oju wa ba r'ewa ogo Re 

   Ni ebute ti a fi wura ko

   A o duro lor'idakoro wa 

   Gbogbo iji yoo re wa koja.

Egbe: ldakoro n be fun okan wa 

      B’o ti wu ki iji naa le to

      Jesu l’Apata ti ko le ye 

      Lor’Apata ife Re l'a n duro. Amin

English »

Update Hymn