HYMN 503

8.7.8.7.D.
“Ore mi li eyin ise" - Jn 15:14
1. ORE wo l’a ni bi Jesu

   Ti O ru ‘banuje wa 

   Anfaani wo I’o po bayi 

   Lati maa gbadura si I 

   Alaafia pupo l’a n sonu 

   Iror’ainidi l’a n je

   ‘Tori a ko n fi gbogbo nnkan 

   S’adura niwaju Re.


2. Idanwo ha wa fun wa bi? 

   A ha ni wahala bi

   A ko gbodo so ‘reti nu 

   Sa gbadura s‘Oluwa,

   A'a le ri ore olooto 

   Ti o Ie ba wa daro 

   Jesu ti mo ailera wa, 

   Sa gbadura s'Oluwa.


3. Eru han won wa l'orun bi? 

   Aniyan ha po fun wa? 

   Olugbala ni aabo wa,

   Sa gbadura s‘Oluwa 

   Awon ore ha sa o ti?

   Sa gbadura s’Oluwa

   Yoo gbe o soke l’apa Re, 

   lwo yoo si n'itunu. Amin

English »

Update Hymn