HYMN 504

PM S.S. (FE 532)
"Ajagun Oba" - 2Tim. 2:3
1. AWA omo ogun Oba ti a f’eje Re ra

   A si mura lati jagun fun Kristi Oluwa 

   A ngb’arin ota wa, sugbon

   a nf'ayo korin

   Okan wa yio duro gbonyin-gbonyin.

Egbe: Awa omo ogun Oba 

      A o korin iyin Re

      A o si ja tokan‐tokan 

      F'Oba Ologo julo.


2. Aw’omo ogun Oba, a o f‘ayo j'oko Re 

   O ko eniti a kan mo ‘gi

   gba Kristi Oba wa mbe

   Adanu l'ere aiye ao f'ayo gba iya

   lati bowo f’oruko Re, b‘ omo ogun Oba.

Egbe: Awa omo ogun Oba...


3. Awa omo ogun Oba, ao jade pelu Re 

   Bi awa ba le jiya, k’a si ru itiju

   K‘a gb’asia Re ga, ‘tori akoko nlo

   A ti gba ade nsunmole

   f‘awon omo ogun Oba.

Egbe: Awa omo ogun Oba 

      A o korin iyin Re

      A o si ja tokan‐tokan 

      F'Oba Ologo julo. Amin

English »

Update Hymn