HYMN 505

(FE 533)
Ohun Orin: Ru iti wole1. GBOGBO Egbe Seraf to wa ni

   gbogb‘aiye

   E sin Olugbala l'emi at‘oto 

   E fi keta sile, e feran ara nyin 

   Gbogbo wa ni Jesu

   Olugbala npe.

Egbe: Wa k'a jumo rin, wa k'a jumo rin 

      Wa si Egbe Seraf ati kerubu 

      Wa k'a jumo rin, wa

      k'a jumo rin

      Wa si Egbe Seraf' wa gb’emi re Ia.


2. Nigbat‘ aiye ti se ti awa ti d‘aiye 

   A gbo wipe Jesu lo segun Esu 

   Awa Egbe Seraf’ y‘o si segun Esu 

   Li Oruko Olorun Metalokan.

Egbe: Wa k'a jumo rin...


3. Awa Aje, Oso, ko ni agbara kan 

   Lori Egbe Seraf‘ati Kerubu 

   Egbe aladura, e damure giri

   K’a le segun Esu pelu ogun re. 

Egbe: Wa k'a jumo rin...


4. Enyin Egbe Akorin,

   E tun ohun nyin se

   Lati yin Olugbala wa li ogo 

   Gbogb‘awon t'o ti ja

   nwon si segun esu

   Mura k‘enyin na le segun bi ti won, 

Egbe: Wa k'a jumo rin...


5. Aiye le ma kegan, nwon si

   le ma sata,

   Sugbon Serafu mo Ent‘on nsin 

   lwo m’Eniti o nsin,

   Enit’ o nsin mo o

   Sa tejumo Jesu, iwo yio segun. 

Egbe: Wa k'a jumo rin...


6. Nigbat‘a ba pari ise wa ni aiye

   A o gb’ade lehin irin ajo wa

   Jesu Olugbala, yio ko wa de kenian 

   Ile ileri na ti Oga Ogo.

Egbe: Wa k'a jumo rin, wa k'a jumo rin 

      Wa si Egbe Seraf ati kerubu 

      Wa k'a jumo rin, wa

      k'a jumo rin

      Wa si Egbe Seraf' wa gb’emi re Ia. Amin

English »

Update Hymn