HYMN 508

(FE 536)
"Olorun igbala wa" - Ps. 65:5


1. OLORUN t’o gbo ti Dafidi
 
   Lori awon Ota re 

   Olorun to gbo ti Esther 

   T’o si segun Hamani. 

Egbe: Gb’adura wa, Oba olore 

      Gege bi a ti nke pe O 

      Mase je k’omo Re rahun 

      L'a tunbotan aiye wa.


2. Hosanna Oba Ologo 

   Kabiyesi f ’Oba wa, 

   F’ebun ore-ofe Re fun wa 

   K’awa le sin O d’opin. 

Egbe: Gb’adura wa...


3. Olorun to gbo ti Hanna 

   Jowo gbo t’awon agan wa 

   Olorun to gbo ti Serah 

   Sanu f’awa omo Re.

Egbe: Gb’adura wa...


4. Awa Omo Egbe Serafu 

   Ti aginju aiye yi

   F'ebun Emi Mimo Re fun wa,

   K‘a wa le jere ade.

Egbe: Gb’adura wa...


5. Olorun to gbo Elija 

   Leba odo Jodan 

   Olorun to gbo ti Mose 

   Lori oke Sinai. 

Egbe: Gb’adura wa...


6. B'o ti wu k' orun ko mu to 

   Sanma dudu die yio wa 

   B'o ti wu k'aiye wa l'ayo 

   Yo n’ akoko ekun re. 

Egbe: Gb’adura wa...


7. L’ohun kan gbogbo wa kunle 

   Pa ese run l'okan wa

   F’ebun meje orun Re fun wa, 

   Ki ‘fe wa le ma po si.

Egbe: Gb’adura wa, Oba olore 

      Gege bi a ti nke pe O 

      Mase je k’omo Re rahun 

      L'a tunbotan aiye wa. Amin

English »

Update Hymn