HYMN 509

H.C. 4366 8s. 7s (FE 537)
“Oluwa yio ja fun nyin" - Eks.14:141. OM'OGBE Kerubu jade 

   Gbogbo aje pagan mo 

   Awa Serafu l'o pejo 

   Lati gb’ogo Jesu ga. 

Egbe: Maikeli Mimo

      Ni Balogun Egbe wa.

      Maikeli Mimo

      Ni Balogun Egbe wa.


2. Aje ko Ie ri wa gbese 

   Labe opagun Jesu 

   Niwaju awon Serafu 

   Gbogbo aje a fo lo.

Egbe: Maikeli Mimo...


3. Idarudapo yio b’aje 

   Niwaju ogun Jesu 

   ldaj’Olorun de be won 

   Lagbara Metalokan. 

Egbe: Maikeli Mimo...


4. Halleluya! Halleluya! 

   Jek’a ko Halleluyah 

   Ajekaje ko lagbara 

   Lori Egbe Kerubu. 

Egbe: Maikeli Mimo...


5. Gidigbo, gidigbo heyah 

   A p'awon aje n'ija

   Ati soponna baba won 

   Loruko Metalokan. 

Egbe: Maikeli Mimo...


6. E f'ogo fun baba loke

   E f’ogo fun Omo Re 

   E.f’ogo fun Emi Mimo

   F’ ogo fun Metalokan.

Egbe: Maikeli Mimo

      Ni Balogun Egbe wa.

      Maikeli Mimo

      Ni Balogun Egbe wa. Amin

English »

Update Hymn