HYMN 511

1. AH! ojo iyanu ojo ’yanu

   Ojo ti n ko le gbagbe

   Gba mo sako lo ninu okunkun 

   Ni mo ba Jesu pade

   Ore olufe, Eni ikaanu

   B'okan aini mi pade

   O mu beru lo, pel'ayo ni mo n rohin 

   O mu ghogb' okunkun lo! 

Egbe: Ogo orun si kun ‘nu okan mi

      Gba t’Olugbala so mi di pipe 

      A we ese mi nu, ale mi si d'owuro 

     Ogo orun si kun 'nu okan mi.


2. A bi mi nipa Emi pelu ye 

   Sinu ebi Olorun

   A da mi lare nipa 'fe Kristi 

   Mo ni‘gbekele t’o ga

   Ise naa di sise logan nigba

   Ti mo wa bi elese

   Mo gba ebun oor-ofe eyi t’O mu wa

   O gba mi, yin Ooko Re.

Egbe: Ogo orun si kun ‘nu...


3. Nisin yi mo n’ireti t’o wa lae 

   Lehin opin ajo mi

   O daju pe mo n’ireti l’orun 

   N’ile ologo julo

   Ati nitori ojo yanu ni

   Ti mo wole l'ese Re

  Oro ainipekun ibukun l’atorun 

  Ti mo gba ni owo Re.

Egbe: Ogo orun si kun ‘nu okan mi

      Gba t’Olugbala so mi di pipe 

      A we ese mi nu, ale mi si d'owuro 

     Ogo orun si kun 'nu okan mi. Amin

English »

Update Hymn