HYMN 513

H.C 326 6 8S (FE 538)
"Ngo fe O, Oluwa agbara mi" - Ps.18:11. NGO feran Re, wo odi mi 

   Ngo feran Re, wo ayo mi 

   Ngo feran Re, patapata 

   Ngo feran Re, tor’ise Re 

   Ngo feran Re, tit’ okan mi 

   Y’o fi kun fun ife rere.


2. Wo Orun mi, gba ope mi 

   Fun mole Re t’o fi fun mi 

   Gba ope mi, wo l‘o gba mi 

   lowo awon ti nsota mi 

   Gba ope mi, fun ohun Re 

   To mu mi yo lopolopo.


3. N’nu ire-ije mi l’aiye

   Ma se alabojuto mi

   Fi agbara fun ese mi

   Ki nle t’ese m'ona rere

   Ki mba le f’ipa mi gbogbo 

   F’oruko Re t‘o l’ogo han.


4. Ngo feran Re, Wo ade mi 

   Ngo feran Re, Oluwa mi 

   Ngo feran Re, nigbagbogbo 

   L’ojo ibi, l’ojo ire

   Gbati ojo iku ba de

   Ngo feran Re titi lailai. Amin

English »

Update Hymn