HYMN 515

CMS 331 H.C 318 (FE 540)
“Oruko Re dabi ikunra ti a tu jade”
- Orin Sol. 1:31. B’ORUKO Jesu ti dun to 

   Leti onigbagbo!

  O tan banuje on ogbe

  O si le eru lo.


2. O wo okan to gbogbe san 

   O mu aiya bale

   Manna ni fun okan ebi 

   Isimi f'alare.


3. Apata ti mo kole le 

   Ibi isadi mi

   Ile isura mi t’o kun 

   F’opo ore-ofe.


4. Jesu, Oko mi, Ore mi 

   Woli mi, Oba mi 

   Alufa mi, Ona, Iye 

  Gba orin iyin mi.


5. Ailera l’agbara ‘nu mi 

   Tutu si l'ero mi

   Gba mo ba ri O b’O ti ri 

   Ngo yin O b'o ti ye.


6. Tit’igbana ni ohun mi 

   Y’o ma rohin ‘fe Re 

   Nigba iku, k’Oruko Re 

   F’itura f’okan mi. Amin

English »

Update Hymn