HYMN 516

C.M.S 332 H.C 321 C.M (FE 541)
"Ife Krist li o nro wa" 2Kor.5:14.
1. OLUGBALA mi, ife Re 

   Ha tobi be si mi

   Wo mo f’ile mi, okan mi 

   At'aiya mi fun O.


2. Mo fe O nitori ‘toye 

   Ti mo ri ninu Re 

   Mo fe O nitori iya 

   T‘o f'ara da fun mi.


3. Bi Iwo ti je Olorun 

   T'a f’ogo de l’ade 

   Iwo ko ko awo enia 

   T’o kun fun iyonu.


4. Wo je k’a bi O l’enia 

   Sugbon ‘Wo ko l’ese 

   K’awa le ri b‘Iwo ti ri 

   K’a le se b'O ti se.


5. K’a dabi Re ninu ife 

   L’ewa iwa mimo

   B’a ti nwoju Re, k’a ma lo 

   Lat’ogo de ogo. Amin

English »

Update Hymn