HYMN 517

H.C 320 D.C.M (FE 542) 
"Kristi ninu nyin, ireti ogo"
- Kol. 1:271. IFE orun, alailegbe

   Ayo orun, sokale

   Fi okan wa se ‘bugbe Re 

   Se asetan anu Re

   Jesu, iwo ni alanu

   Iwo l’onibu ife

   Fi gbala Re be wa wo 

   M‘okan eru wa duro.


2. Wa, Olodumare, gba wa 

   Fun wa l’ore-ofe Re 

   Lojiji ni k’o pade wa 

   Ma si fi wa sile mo 

   Iwo l'a o ma yin titi

   Bi nwon ti nse ni orun 

   Iyin wa ki yio l’opin 

   A o sogo n’nu ‘fe re.


3. Sasepe awa eda Re 

   Jek‘a wa lailabawon 

   K’a ri titobi gbala Re 

   Li aritan ninu Re

   Mu wa lat‘ogo de ogo 

   Titi de ibugbe wa

   Titi awa o fi wole 

   N‘iyanu ife, iyin. Amin

English »

Update Hymn