HYMN 521

H.C 319 7s (FE 546)
"Iwo fe mi bi?" - John 21:161. OKAN mi, Oluwa ni 

   Jesu re ni, gboro Re 

   Jesu nso, O mba o so 

   Pe, elese ‘Wo fe mi?


2. Gbat‘ a de o, Mo da o

   O gb’ogbe, Mo wo o san 

   Gb’ o sako, Mo mu o bo 

   Mo s’okun re d'imole.


3. Kike iya ha le mo

   Si omo re ti o bi? 

   Lotito o le gbagbe 

   Sugbon Em’o ranti re.


4. Ife t'Emi ki ye lai 

   O ga rekoja orun 

   O si jin ju okun lo 

   Ife alailegbe ni.


5. Wo fere r’ogo Mi na 

   Gb’ise ore-ofe tan 

   Wo o ba Mi gunwa po 

   Wi, elese, wo fe mi?


6. Olori aroye mi

   Ni pe ife mi tutu

   Sugbon mo fe O Jesu

   A! mba le fe O ju yi!. Amin

English »

Update Hymn