HYMN 522

H.C 314 6 8s (FE 547)
“E duro ninu ife mi"- Joh.15:91. JESU Oluwa, Oba mi 

   Gbohun mi nigbati mo npe, 

   Gbohun mi lati ‘bugbe Re, 

   Rojo ore-ofe sile.

Egbe: Oluwa mi, mo feran Re 

      Jeki nle ma feran Re si.


2. Jesu mo ti jafara ju 

   Ngo se le fe O, b’o ti ye 

   Em’ o se le gb’ogo Re ga 

   Ati ewa oruko Re.

Egbe: Oluwa mi...


3. Jesu, kil’o ri ninu mi 

   Ti ‘fe na fi po to bayi

   Ore Re si mi ti po to! 

   O ta gbogbo ero mi yo! 

Egbe: Oluwa mi...


4. Jesu, ‘Wo o je orin mi

   Tire l’aiye at’okan mi

   Tire ni gbogbo ini mi 

   Olugbala, Wo ni temi.

Egbe: Oluwa mi, mo feran Re 

      Jeki nle ma feran Re si. Amin

English »

Update Hymn