HYMN 523

S.192 P.M (FE 548)
"Beni Oluwa iwo mo pe mo 
fe O" - John 21:151. KI nfe O si, Kristi! ki nfe O si 

   Gb’adura ti mo gba lor’ekun mi 

   Eyi ni ebe mi: Ki nfe O si Kristi 

   Ki nfe O si! ki nfe O si.


2. Lekan, ohun aiye ni mo ntoro 

   Nisisiyi, ‘Wo nikan ni mo nwa 

   Eyi l'adura mi: ki nfe O si, Kristi 

   Ki nfe O si! ki nfe O si!


3. Jeki banuje de, at'irora 

   Didun l’ojise Re, at’ise won 

   Gba nwon mba mi korin

   Ki nfe o si Kristi

   Ki nfe o si! ki nfe O si!


4. Nje opin emi mi y'o w’iyin Re 

   Eyi ni y'o je ore kehin Re 

   Adura na o je: Ki nfe O si Kristi! 

   Ki nfe O si! Ki nfe O si. Amin

English »

Update Hymn