HYMN 525

C.M.S 336 H.C 328 t. H.C 
449 6. 7s (FE 550)
"Ara, ajigbese Ii awa" - Rom. 8:121. GBAT‘AYE yi ba koja 

   T’orun re ba si won 

   Ti a ba won ‘nu ogo

   T‘a boju wo ehin wa 

   Gbana, Oluwa, ngo mo 

   Bi gbese mi ti po to.


2. Gba mo ba de b’ite Re 

   Lewa ti ki se t’emi 

   Gba mo ri O b’O ti ri 

   Ti mo fe O l'afetan 

   Ghana, Oluwa ngo mo 

   Bi gbese mi ti po to.


3. Gba mba ngbo orin orun 

   Ti ndun bi ohun ara

   Bi iro omi pupo

   To o si ndun b’ohun duru 

   Gbana, Oluwa, ngo mo

   Bi gbese mi to po to.


4. Oluwa, jo, je k'a ri 

   Ojiji Re l’aiye yi 

   K’a mo adun ‘dariji 

   Pelu iranwo Emi

   Ki ntile mo l‘aiye yi 

   Die ninu ‘gbese mi.


5. Ore-ofe l’o yan mi

   L’o yo mi ninu ewu

   Jesu l‘Olugbala mi

   Emi so mi di mimo

   Ko mi, ki nfihan l’aiye,

   Bi gbese mi ti po to!. Amin

English »

Update Hymn