HYMN 531

1. MO fe jinle si i ninu ‘fe Jesu

   Ni ojoojumo

   Ki n dagba si n‘ile eko ogbon 

   At’oor-ofe Re.

Egbe: Mo fe.. maa jinle si

      Ki n ga.. sii n’joojumo 

      Ki n si..ni ogbon sii 

      N’nu oro yebiye Re.


2. Mo fe jinle iwo Emi Mimo 

   Mu mi jinle sii

   Ti gbogb'aye mi yoo je ti Jesu 

   Ati ife Re. 

Egbe: Mo fe.. maa jinle si...


3. Mo fe jinle, b'idanwo tile de

   Mu mi jinle si i

   Ki n fi gbongbo mule n'nu ‘fe Jesu 

   Jeki n’ s'eso si i.

Egbe: Mo fe.. maa jinle si...


4. Ki n jinle, ki n dagba ninu Jesu 

   Tit'ija yoo tan 

   Si se mi ni asegun bi i ti Re 

   Titi de opin.

Egbe: Mo fe.. maa jinle si

      Ki n ga.. sii n’joojumo 

      Ki n si..ni ogbon sii 

      N’nu oro yebiye Re. Amin

English »

Update Hymn