HYMN 532

O.t.S 670 S.M. (FE 558)
“Nkan wonyi ni mo palase fun nyin pe 
ki enyin ki o fe omomikeji nyin"
 - John 15:17
1. FE enikeji re

   Ase Oluwa ni

   O wa f‘ara Re s'apere 

   Ni ifefe t'O fe wa.


2. Fe enikeji re"

   N’ire tabi n’ija

   O ko wa pe k’a f'ota wa 

   K’a f’ore san ibi.


3. Fe enikeji re’

   Oluwa nke tantan

   O ye ki gbogbo wa mura 

   K’a f 'enikeji wa.


4. Fe enikeji re 

   At’aladugbo re

   Pelu gbogb’eni yi o ka 

   At' ota re pelu.


5. K‘a f'enikeji wa

   Bi Jesu ti fe wa

   Jesu sa f'awon ota Re 

   O si sure fun won. Amin

English »

Update Hymn