HYMN 534

(FE 560)
"E duro ninu ife Mi" - John15:91. KERUBU ati Serafu 

   E feran ara nyin 

   Gege bi awon ti orun 

   Ti feran ara won.

Egbe: K‘a gbekele Jesu Kristi 

      Oluwa Mima ni

      Bi mo ti ni ife Jesus 

      Emi ko le segbe.


2. Ota po fun wa li laiye 

   Ko si alabaro

   Jesu l’Olubanidaro 

   On na lo le gba wa 

Egbe: K‘a gbekele Jesu...


3. Esu ti korira wa 

   O fe mu wa dani 

   Sugbon ewo la o se 

   Jesu ti pelu wa.

Egbe: K‘a gbekele Jesu...


4. Jesu ti segun esu 

   L’or’oke Kalfari 

   Oluwa segun fun wa 

   Ka le bori ota wa. 

Egbe: K‘a gbekele Jesu...


5. Olorun Orimolade 

   Jowo sanu fun wa 

   K‘O gba wa low‘ota wa 

   Ni ona wa gbogbo.

Egbe: K‘a gbekele Jesu...


6. Li akoko iku wa

   Mu ki okan wa mo 

   Ka ba le lo ri Jesu 

   Lodo Baba loke.

Egbe: K‘a gbekele Jesu...


7. A ki Baba Aladura 

   Ti baba gbe dide

   Ki Jesu ko ran lowo 

   Ko gbe owo re soke.

Egbe: K‘a gbekele Jesu...


8. Jehovah Rufi, Baba 

   Gb'adura ljo yi 

   Jehovah Jire Mimo 

   K’O mese wa duro.

Egbe: K‘a gbekele Jesu...


9. Enyin egbe Aladura 

   E mura si ise nyin 

   K’e n‘ife si ara nyin 

   Baba yio gbo ti nyin.

Egbe: K‘a gbekele Jesu...


10. A f’ogo fun Baba loke 

    A f'ogo f'Omo Re

    A f’ogo F'Emi Mimo

    Metalokan lailai.

Egbe: K‘a gbekele Jesu Kristi 

      Oluwa Mima ni

      Bi mo ti ni ife Jesus 

      Emi ko le segbe. Amen

English »

Update Hymn