HYMN 538

H.C. 341 L.M (FE 564)
“Bere ohun ti Emi o fi fun o” 1Oba.3:51. OLUWA, Iwo ha wipe

   Ki mbere ohun ti mo nfe? 

   Jo, jeki mbo lowo ebi

   Ati low’ese on Esu.


2. Jo, fi ara Re han fun mi 

   Si jeki nru aworan Re 

   Te ite Re si okan mi 

   Si ma nikan joba nibe.


3. Jeki nmo p’O dariji mi 

   Ki ayo Re s’agbara mi

   Ki nmo giga, ibu, jijin 

   Ati gigun ife nla Re.


4. Eyi nikan ni ebe mi

   Eyit’ O ku di owo Re

   lye, iku, aini, oro

   Ko je nkan, b’O ba je temi. Amin

English »

Update Hymn