HYMN 539

t.H.C 154 C.M (FE 565)
"Awon ti o ti gba opolopo ore-ofe ati 
ebun ododo, yio joba ninu iye nipa 
enikan Jesu Kristi" - Rom.5:17
Tune: Amazing Grace.1. OORE-OFE-B’ o ti dun to 

   To gba em‘ abosi

   Mo ti sonu, o wa mi ri 

   O si si mi loju.


2. Or’ofe ko mi ki ‘m‘ beru 

   O si l’eru mi lo 

   B’ore-ofe na ti han to 

   Nigba mo ko gbagbo!


3. Opo ewu at’idekun

   Ni mo ti la koja

   Or’ofe npa mi mo d‘oni 

   Y’o si sin mi de’le.


4. Nje gbat' ara at‘okan ye 

   Ti emi ba si pin

   Ngo gb’ayo at’alafia 

   Loke orun lohun. Amin

English »

Update Hymn