HYMN 54

(FE 71)
“Oluwa ranti mi" - Luku 23:421. BABA jo ranti mi,

   Ni ‘ile Mimo Ioke 

   Jo gba mi ki nje tire, 

   S'ile Mimo loke.

Egbe: Oluwa ranti mi, 

      Oluwa ranti mi,

      Gbat'O ba de joba Re, 

      Oluwa ranti mi.


2. Elese jo ronu 

   K‘akoko to koja 

   Akoko koja f’ole 

   To wa lowo osi 

Egbe: Oluwa ranti mi...


3. Okan mi ji giri, 

   K‘akoko to koja

   Ki ilekun anu re se; 

   Oluwa ranti mi 

Egbe: Oluwa ranti mi...


4. Ironupiwada
 
   Ni Kristi fe wa fun 

   Ka le ni ayo kikun 

   N'ile baba loke 

Egbe: Oluwa ranti mi...


5. Jesu jo ranti mi,

   Gba emi elese

   Gbat' O ba de ijoba Re, 

   Ni' le Paradise.

Egbe: Oluwa ranti mi...


6. Orin Alleluya,

   L’awa yio ko lorun 

   Gbat‘ a ba de ite Baba, 

   N'ife Mimo loke 

Egbe: Oluwa ranti mi...


7. Ogo ni fun Baba, 

   Ogo ni fun Omo, 

   Ogo ni f‘Emi Mimo 

   Metalokan lailai.

Egbe: Oluwa ranti mi... Amin

English »

Update Hymn