HYMN 540

H.C.30 D.C.M. (FE 566) 
"Nitori awa ti o wa ninu ago yi
nkerora, eru npa nwa" - 2Kor.5:41. EWA ‘tanna oro kutu

   Mole osan gangan

   Pipon orun Ii ojoro 

   Nwon ti nyara sa to 

   A nfe enubode orun

   Ita wura didan

   Awa nfe Orun Ododo 

   Ti ki wo titi lai.


2. B'ireti giga wa laiye 

   Ti ntete saki to! 

   Abawon melomelo ni 

   Nb’agbada Kristian je? 

   A nfe okan ti ki dese 

   Okan ti a we mo 

   Ohun lati yin Oba wa 

   Losan-loru titi.


3. Nihin ‘gbagbo on’reti mbe 

   Lati to wa soke

   Lohun, pipe alafia

   Ju b’a ti le fe lo

   Nipa ife on ‘rora Re,
  
   Nitori iku Re 

   Ma jek'a subu lona Re

   K'a so ade wa nu. Amin

English »

Update Hymn