HYMN 541

H.C 417 t.H.C 120 D. 8s.7s (FE 567)
“Ohunkohun ti o jasi ere fun mi awon 
ni mo ka s'ofo nitori Kristi” - Filip. 3:71. JESU mo gb’agbelebu mi,

   Ki nle ma to O lehin

   Otosi at'eni egan

   Wo l’ohun gbogbo fun mi 

  Bi ini mi gbogbo segbe 

  Ti ero mi gbogbo pin 

  Sibe oloro ni mo je!

  Temi ni Krisit' at’Orun.


2. Eda le ma wahala mi

   Y'o mu mi sunmo O ni 

  ldanwo aiye le ba mi 

  Orun o mu ‘simi wa 

  lbanuje ko le se nkan 

  B'ife R eba wa fun mi 

  Ayo ko si le dun mo mi 

  B’Iwo ko si ninu re.


3. Okan mi, gba igbala re 

   Bori ese at’eru 

   F'ayo a wa ni ipokipo 

   Ma sise, si ma jiya 

   Ro t’Emi t’o wa ninu re? 

   At'ife Baba si O 

   W’Olugbala t'o ku fun o 

   Omo orun, ma se kun!


4. Nje koja lat'ore s’ogo 

   N'n'adura on igbagbo 

   Ojo ailopin wa fun O 

   Baba y‘o mu o de be

   lse re l'aiye fere pin

   Ojo ajo re mbuse

   lreti y'o pada s'ayo 

   Adura s‘orin iyin. Amin

English »

Update Hymn