HYMN 544

H.C 404 8s 7s (FE 570)
‘O si wi fun won pe, E ma to mi Iehin"
- Matt. 4:19-20
1. JESU npe wa, losan loru 

   Latin irumi aiye 

   Lojojumo l‘a ngbohun Re 

   Wipe, ‘Kristian, tele Mi‘.


2. Awon Aposteli gbani

   Ni odi Galili ni 

   Nwon ko ile, ona sile 

   Gbogbo nwon si nto lehin.


3. Jesu npe we, kuro ninu 

   Ohun aiye asan yi

   L’arin afe aiye, O nwi 

   Pe, “Kristian e feran Mi".


4. Larin ayo at'ekun wa 

   Larin lala on ‘rorun

   Tantan l'o npe l'ohun rara 

   Pe, “Kristian e feran Mi".


5. Olugbala nip'anu Re 

   Jeki a gbo ipe Re

   F'eti ‘gboran fun gbogbo wa, 

   K'a fe O ju aiye Io. Amin

English »

Update Hymn