HYMN 546

C.M.S 432 H.C 434 t.A. & M.323 
C.M (FE 572)
“E ma se eyi ni iranti Mi"
 - Luku.22:19


1. GEGE bi oro ore Re 

   Ninu irele nla

   Emi o s'eyi, Oluwa 

   Emi o ranti re.


2. Ara Re ti a bu fun mi 

   Yio je onje mi

   Mo gba ago majemu Re 

   Lati se ranti re.


3. Mo le gbagbe Gestsemane 

   Ti mo r’ijanu Re 

   Iya on ogun eje Re

   Ki nma si ranti re.


4. Ngo ranti gbogbo rora Re 

   Ati ‘fe Re si mi

   Bi o ku emi kan fun mi 

   Emi o ranti Re.


5. Gbati enu mi ba pamo 

   Ti iye mi ba ra

   Ti O ba de n'ljoba Re 

   Jesu, jo ranti mi. Amin

English »

Update Hymn