HYMN 547

C.M.S 431 H.C 435 t.H.C 41 
L.M (FE 573)
“Emi lanje iye ni” - John.6:481. JESU, ayo okan gbogbo 

   Orisun 'ye imole wa

   Nin' opo bukun aiye yi 

   Lainitelorun: a to wa.


2. Otito re duro lailai

   Won gba awon to ke pe O la

   Awon ti owa O, ri O

   Bi gbogbo nin'ohun gbogbo.


3. A to O we, Onje iye

   A fe je l'ara Re titi

   A mu ninu Re, Orisun 

   Lati pa ongbe okan wa.


4. Ongbe Re sa ngbe okan wa 

   Nibikibi t‘ o wu k'a wa 

   Ghat' a ba ri O awa yo 

   Ayo nigbat’a gba O gbo.


5. Jesu, wa ba wa gbe titi

   Se akoko wa ni rere

   Le okunkun ese kuro 

   Tan ‘mole re mimo s’aiye. Amin

English »

Update Hymn