HYMN 549

C.M.S 435 H.C 339 L.M (FE 575)
"Awa o lo sinu ago, Re awa o ma 
sin nibi apoti agbara Re" - Ps.132:7
1. ODO-Agutan Olorun

   Jo we mi ninu eje Re

   Sa je ki nmo ‘fe Re, gbana 

   lrora dun, iku lere.


2. Fa okan mi kuro l‘aiye 

   K'o je k'o se Tire titi 

   Fi edidi Re s'aiya mi 

   Edid’ife titi aiye.


3. A! awon wonni ti yo to

   To f’iha Re se 'sadi won 

   Nwon fi O se agbara won

   Nwon nje, nwon si nmu ninu Re.


4. O kun wa loju p’Olorun 

   Fe m' awa yi lo sin ‘ogo 

   Pa, O so eru d’om‘Oba 

   Lati ma je faji lailai.


5. Babe, mu wa ronu jinle

   K‘a le mo ise nlanla Re

   Ma sai tu okun ahon wa

   K’a le so ibu ife re.


6. Jesu, Iwo l’Olori wa,

   Wo lao teri wa ba fun

   Wo l’ao fi okan wa fun

   B’a ku, b’a wa, k’a je Tire. Amin

English »

Update Hymn