HYMN 550

(FE 577)
1. ENYIN ara ati ojulumo

   E wa wole ki le ayo to kun

   Gbogbo aiye ni Jesu npe tantan 

   Wa wo oko igbala yi ki o to kun.

Egbe: Yara wa, wa wole)

      Jesu lo npe nyin tantan). 3ce

      Ki oko Noah ikehin 

      yi ko to kun tan.

 
2. Gbogbo Egbe at’Ijo Olorun 

   Keferi ati Imale ilu

   Gbogbo aiye ni Jesu npe tantan 

   Wa wo oko igbala yi ki o to kun. 

Egbe: Yara wa, wa wole...


3. Ijo Afrika wa ba wa josin 

   Ati gbogbo ljo Omo ‘bile 

   Jesu Kristi’ lo wipe ki e wa

   Wa wo oko igbala yi ki o to kun. 

Egbe: Yara wa, wa wole...


4. Olorun Shedrack lo npe nyin tantan 

   Olorun Mesak lo npe nyin tantan 

   Olorun Abednego lo npe nyin

   Wa wo oko igbala yi ki o to kun. 

Egbe: Yara wa, wa wole...


5. Olorun Abram lo npe nyin tantan 

   Olorun Isaac lo npe yin tantan 

   Olorun Jacob lo npe nyin tantan 

   Wa wo oko igbala yi ki o to kun. 

Egbe: Yara wa, wa wole...


6. Olorun Dafidi lo npe nyin tantan 

   Olorun Daniel lo npe nyin tantan 

   Olorun Batimeu lo npe nyin tantan 

   Wa wo oko igbala yi ki o to kun. 

Egbe: Yara wa, wa wole...


7. Olorun Mary lo npe nyin tantan 

   Olorun Martha lo npe nyin tantan 

   Olorun Esther lo npe nyin tantan 

   Wa wo oko igbala yi ki o to kun. 

Egbe: Yara wa, wa wole...


8. Kerubu ati Serafu lo npe nyin 

   Eni Mime, Israeli lo npe nyin 

   Gbogbo Ogun Orun lo ni k'e wa 

   Wa wo oko igbala yi ki o to kun. 

Egbe: Yara wa, wa wole)

      Jesu lo npe nyin tantan). 3ce

      Ki oko Noah ikehin 

      yi ko to kun tan. Amin


English »

Update Hymn