HYMN 555

(FE 582)
“Se giri ki o si mu aiya le” - Jos.1:91. JESU ni Balogun oko 

   E mase jek’ a foiya

   Olutoko wa ni Jesu 

   E mase jek’a foiya.

Egbe: E mase beru

      E kun fun ayo 

      Nitori Jesu I’oga oko 

      Bo ti wu ki ji na le to 

      Yio mu oko wa gunle.


2. Enyin ero to wa l’oko

   E ke pe Jesu nikan

   K’e si gbekele nyin le pelu 

   Yio mu oko wa gunle. 

Egbe: E mase beru...


3. Olugbala Wo t’oro re 

   Mu igb’omi pa roro 

   Iwo t’o orin lori omi 

   T‘o sun beni ko si nkan.

Egbe: E mase beru...


4. Kil’ohun to mba nyin leru? 

   Enyin Omogun Kristi

   Bi Jesu ba wa ‘nu oko

   Awa yio fi ‘gbi rerin.

Egbe: E mase beru...


5. Gbati gbi aiye yi ba nja 

   Lor‘okun ati nile

   Abo kan mbe ti o daju 

   Lodo Olugbala wa.

Egbe: E mase beru...


6. Lowo Kiniun at‘ekun 

   Lowo eranko ibi 

   Jesu yio dabobo tire 

   Jesu yio pa tire mo.

Egbe: E mase beru...


7. Metalokan Alagbara 

   Dabobo awa omo re 

   Lowo ategun ati iji

   Jek’awa k’ alleluya. 

Egbe: E mase beru...


8. Ogo ni fun Baba loke 

   Ogo ni fun Omo Re 

   Ogo ni fun Emi Mimo

   Metalokan l’ope ye.

Egbe: E mase beru

      E kun fun ayo 

      Nitori Jesu I’oga oko 

      Bo ti wu ki ji na le to 

      Yio mu oko wa gunle. Amin

English »

Update Hymn