HYMN 556

C.M.S 359 H.C 366 8s 7s 
(FE 583)
"Nwon jewo pe, alejo ati atipo
li awon lori ile aiye" - Heb.11:131. MA toju mi Jehofa nla

   Ero l’aiye osi yi

   Emi ko n’okun, Iwo ni 

   F’ow’agbara di mi mu 

   Onje orun, Onje orun

   Ma bo mi titi lailai.


2. Silekun isun ogo ni 

   Orisun imarale

   Je ki imole Re orun 

   Se amona mi jale 

   Olugbala, Olugbala 

   S’agbara at’asa mi.


3. Gba mo ba te eba Jordan 

   F'okan eru mi bale 

   Iwo t’o ti segun iku 

   Mu mi gunle Kenaan je 

   Orin iyin,orin iyin 

   L’emi o fun O titi. Amin

English »

Update Hymn