HYMN 557

(FE 584)
"Ilu a tedo lori oke ko Ie f’ara sin"
 - Matt.5:141. AWA n’imole aiye, 

   Kerubu, Serafu

   Ilu ti a ti si oke

   Bawo ni yio ti se farasin.

Egbe: Jek'a sise-Jek'a sise 

      Jek'a sise-Jek'a le ri

      lgbala n’ikehin.


2. Te ‘ti lele lati gbo 

   Oro ife Jesu

   Ti o nke rara wipe

   Ha! Omo wo ha feran mi bi?

Egbe: Jek'a sise...


3. Kerubu on Serafu

   Lo si gbogbo agbaiye 

   Mu aiye gbo oro mi 

   Eni ba gbo y’o ri igbala.

Egbe: Jek'a sise...


4. Enyin ara ati ore

   E wa w’oko ‘gbala yi

   Ti Olorun gbe kale

   Ara w’oko k’ilekun to se.

Egbe: Jek'a sise...


5. E rantj ojo Noa

   Ti eda nse dunia

   Ti eranko fi w’oko 

   nikehin.

Egbe: Jek'a sise...


6. Ohun aiye mb’aiye lo

   E lo ranti aye Lot’

   Sugbon t’igbala lo ju

   Ki a mase k’abamo nikehin.

Egbe: Jek'a sise...


7. Baba jo ran wa lowo 

   K’a le sise re d’opin 

   Ki a gbo ohun na pe

   Kerubu, Serafu, gb’ere Re.

Egbe: Jek'a sise-Jek'a sise 

      Jek'a sise-Jek'a le ri

      lgbala n’ikehin. Amin

English »

Update Hymn