HYMN 559

C.M.S 357 H.C 356 7s.3s (FE 586) 
"E wa lairekoja, e si ma sora si i pelu
adura” - 1Pet.4:71. KRISTIAN, ma ti wa ‘simi 

   Gbo b’Angeli re ti nwi

   Ni arin ota l’o wa

   Ma sora.


2. Ogun orun-apadi

   T’a ko ri nko ra won jo 

   Nwon nso ijafara re 

   Ma sora.


3. Wo ‘hamora ogun re 

   Wo l’osan ati l’oru 

   Esu nba, O nd‘ode re 

   Ma sora.


4. Awon t’o segun saju 

   Nwon nwo wa b’awa ti nja 

   Nwon nfi ohun kan wipe 

   Ma sora.


5. Gbo b’Oluwa re ti wi 

   Eniti iwo feran 

   F’oro Re si okan re 

   Ma sora.


6. Ma sora bi enipe

   Nibe ni ‘segun re wa 

   Gbadura fun ‘ranlowo 

   Ma sora. Amin

English »

Update Hymn