HYMN 560

H.C 370 6s. 4s (FE 587) 
"Alejo ni ile ajeji”
- Eks.2:221. NIHIN mo j'alejo 
 
   Orun n’ile

   Atipo ni mo nse 

  Orun n’ile,

  Ewu on ‘banuje, 

  Wa yi mi kakiri 

  Orun ni ilu mi 

  Orun n’ile.


2. B'iji ba tile nja 

   Orun n’ile 

   Kukuru l’ajo mi 

   Orun n’ile

   Iji lile ti nja

   Fe rekoja lo na 

   Ngo sa de le dandan 

   Orun n’ile.


3. Lodo Ol‘ugbala

   Orun n'ile

   A o se mi logo

   Orun n'ile

   Nib' awon mimo wa 

   Lehin ‘rin-ajo won 

   Ti nwon ni simi won 

  Nibe n'ile.


4. Nje nki o kun, tori 

   Orun n’ile

   Ohun t’o wu ki nri 

   Orun n’ile

   Ngo sa duro dandan 

   L’otun Oluwa mi 

   Orun ni ilu mi 

   Orun n'ile. Amin

English »

Update Hymn