HYMN 561

H.C. 363 8s 7s (FE 588)
“Apoti eri Oluwa siwaju won"
 - Num.10:331. MA toju wa Baba Orun 

   Larin ‘damu aiye yi 

   Pa wa mo k‘o si ma bo wa 

   A ko n’iranwo miran 

   Sugbon gbogbo ‘bukun I'a ni 

   B’Olorun je baba wa.


2. Olugbala, dariji wa 

   lwo sa m'ailera wa 

   Wo ti rin aiye saju wa 

   Wo ti mo ‘se inu re 

   B’en' ikanu at’alare 

   L’O ti la ‘ginju yi ja.


3. Emi Olorun, sokale

   F’ayo orun k‘okan wa

   K’ife dapo mo iya wa 

   At’adun ti ki sun ni

   B'a ba pese fun wa bayi

   Kil' o le mi simi wa? Amin

English »

Update Hymn