HYMN 565

H.C 357 11s (FE 592)
"Nitori Oluwa Olorun re, on ni 
mba o lo" - Dent.31:61. E ma te siwaju, Kristian ologun, 

   Ma tejumo Jesu t'o mbe niwaju 

   Kristi Oluwa wa ni Balogun, wa 

   Wo! asia Re wa niwaju ogun.


Egbe: E ma te siwaju, Kristian ologun 

      Sa tejumo Jesu t’o mbe niwaju.


2. Ni oruko Jesu, ogun Esu sa 

   Nje Kristian ologun, ma nso si segun 

   Orun apadi mi ni hiho iyin 

   Ara, gbohun nyin ga,

   gb’orin nyin soke. 

Egbe: E ma te siwaju... 


3. Bi egbe ogun nla, n'Ijo Olorun 

   Ara, a nrin l'ona t'awon mimo rin 

   A ko ya wa n’ipa, egbe kan ni wa, 

   Okan n'ireti, l’eko okan n’ife.

Egbe: E ma te siwaju... 


4. Ite at’Ijoba, wonyi le parun 

   Sugbon Ijo Jesu y'o wa titi lai, 

   Orun apadi ko le bor'ljo yi

   A n’ileri Kristi, eyi ko le ye.

Egbe: E ma te siwaju... 


5. E ma ba ni kalo, enyin enia 

   D’ohun nyin po mo wa

   l’orin isegun 

   Ogo, iyin, ola fun Kristi Oba 

   Eyi ni y’o ma je orin wa titi.

Egbe: E ma te siwaju, Kristian ologun 

      Sa tejumo Jesu t’o mbe niwaju. Amin

English »

Update Hymn