HYMN 566

H.C 367 t. C. App. 3.6 8S (FE 593)
‘Awon eni irapada Oluwa yio pada 
wa si Stoni ti awon ti orin" - Isa. 35:10
1. AMONA okan at’Oga 

   Awon ero l'ona orun

  Jo ba wa gbe, ani awa 

  T’a gbekele lwo nikan 

  Iwo nikan l’a f’okan so 

  B’a ti nrin l’ona aiye yi.


2. Alejo at‘ero l’a je

   A mo p’aiye ki ise ‘le wa 

   Wawa l’a nrin ‘le osi yi 

   L'aisimi l’a nwa oju Re 

   A nyara s’ilu wa orun

   Ile wa titi lai l’oke.


3. Iwo ti o ru ese wa

   T’o si fi gbogbo re ji wa 

   Nipa Re l’a nlo si Sion

   T’a nduna ile wa orun

   Afin Oba wa ologo

   O nsunmo wa, b’a ti nkorin.


4. Nipa imisi ife Re

   A mu ona ajo wa pon 

  S’idapo Ijo-akobi

  A nrin lo si oke orun

  T‘awa t’ayo ni orin wa 

  Lati pade Balogun wa. Amin

English »

Update Hymn