HYMN 569

C.M.S 371 H.C 536, 8s 6 (FE 596) 
“Tani eyi ti ngoke Iati aginju wa, ti o 
fi ara ti Olufe re?" - Orin Solo: 8:51. JESU mimo, Ore airi 

   Oluranlowo alaini 

   N’nu ayida aiye, ko mi 

   K’emi le romo O.


2. Ki nsa n’idapo mimo yi

   Gba ohun t’O fe ngo kun bi? 

   B’okan mi, b’eka ajara

   Ba sa le romo O.


3. Are ti m‘okan mi pupo 

   Sugbon o wa r’ibi ‘simi 

   Ibukun si de s'okan mi 

   Tori t’o romo O.


4. B'aiye d'ofo mo mi loju 

   B’a gba ore at’ara lo

   Ni suru ati laibohun 

   L’emi o romo O.


5. Gbat’ o k’emi nikansoso

   L'arin idamu aiye yi

   Mo gb’ohun ife jeje na

   Wipe, ‘Sa romo Mi‘.


6. B'are ba fe mu igbagbo 

   T'ireti ba si fe saki

   Ko si ewu fun okan na 

   T'o ba romo O.


7. Ko beru irumi aiye

   Nitori ‘Wo wa nitosi
  
   Ki O si gbon b’iku ba de,

   Tori o romo O.

8. Ire sa ni l’ohun gbogbo 

   Wo agbara at’asa mi

   Olugbala, ki y’o si nkan

   Bi mba ti romo O. Amin

English »

Update Hymn