HYMN 57

H.C 177 T.S 43 P.M (FE 74) 
“Gba awon enia Re la" - Ps. 28:9
Tune: “Mokandinlogorun dubule je"1. GBA WA lojo na t’ ao se ‘dajo aiye,

   K'awa le j'eni ‘tewogba

   Se iranlowo fun wa ka j'eni

   ‘tewogba

   Sibi omi ‘ye t'O pese.

Egbe: Sanu fun wa gbadura wa,

      Ji okan ti ntogbe kuro nin'ese. 2ce


2. Jowo tan imole Re loni Oluwa,

   S'oju awon ti ko riran

   Ni apa Jesu aye wa sibe

   Mase tun wi awawi mo.

Egbe: Sanu fun wa...


3. Enyin lmale ati Keferi,

   E wa gbo ihin rere yi,

   Akoko na mbo t’a o bere lowo re

   Pe ise kini iwo nse?

Egbe: Sanu fun wa...


4. Enyin Egbe Kerubu ati Serafu

   E j‘arowa e ma w'ehin

   Lo wo Isaiah ori ogota,

   Ese kini ati keji.

Egbe: Sanu fun wa...


5. Enyin ero iworan ati enijoko

   Bi‘dajo ba o nin‘ese nko

   E wa si imole ninu Egbe Serafu,

   Ke ba le j’eni ‘tewogba.

Egbe: Sanu fun wa...


6. Gbogbo Omo Egbe t‘o s‘olotito

   Ade ogo ti wa fun nyin,

   Bohubiea Aleakutatabb

   Ko ni jeki gbogbo wa segbe

Egbe: Sanu fun wa...


7. Enyin agan to wa ninu Egbe

   E mura si ‘gbagbo,

   Ki e le ni omo bi Samueli

   Lodo Olodumare.

Egbe: Sanu fun wa...


8. Enyin Alamodi to wa nin‘ Egbe

   Enyin yio si ri 'wosan gba

   Lat’odo onisegun Jerusalemu

   E o ri imularada.

Egbe: Sanu fun wa...


9. Enyin ti e ko ti ri ‘se se,

   Jehofa Jireh yio pese,

   lse rere fun itelorun nyin,

   E o ri tunu gba.

Egbe: Sanu fun wa...


10. Ogo ni fun Baba loke

    Ogo ni fun Omo,

    Ogo ni fun Emi Mimo

    Metalokan lailai.

Egbe: Sanu fun wa... Amin

English »

Update Hymn