HYMN 572

t.G.B 466 (FE 599)
"Iwo ba wa kalo" - Num. 10:291. ENYIN ero nibo l’e nlo 

   T‘enyin t’asia lowo?

   Awa nlo s’orere aiye 

   Lati kede oro na.

Egbe: Awa Om'egbe Serafu 

     Ti Olorun tun gbe dide 

     Awa si njo, awa si nyo)
 
     Fun ore t'a gba lofe). 2ce


2. Enyin agba, enyin ewe

   E ba wa ko orin na

   At’okunrin at’obinrin

   K’a jo jumo juba Re. 

Egbe: Awa Om'egbe Serafu...


3. Enyin Egbe Onigbagbo 

   T’o wa ni gbogbo aiye

   Ka fi keta gbogbo sile 

   K'a f'omonikeji wa. 

Egbe: Awa Om'egbe Serafu...


4. E wa jumo k’egbe lo

   Wa si egbe Serafu 

   Wa ma kalo, wa ma kalo 

   Gbogbo wa ni Jesu npe.

Egbe: Awa Om'egbe Serafu 

     Ti Olorun tun gbe dide 

     Awa si njo, awa si nyo
 
     Fun ore t'a gba lofe.

     Awa si njo, awa si nyo
 
     Fun ore t'a gba lofe. Amin

English »

Update Hymn