HYMN 574

L.M (FE 601)
"Awa ko ni ilu ti o duro pe nihinyi
awa nwa okan ti mbo” - Heb.13:41. A ko ni ‘bugbe kan nihin 

   Eyi ba elese n'nu je,

   Ko ye k’enia mimo kanu 

   Tori nwon nfe simi t’orun.


2. A ko ni ‘bugbe kan nihin 

   O buru b'ihin je le wa 

   K’iro yi mu inu wa dun 

   Awa nwa ilu nla t’o mbo.


3. A ko ni ‘bugbe kan nihin 

   A nwa ilu nla t’a ko ri 

   K’iro yi mu inu wa dun 

   Awa nwa ilu nla t'o mbo.


4. Iwo ti nse ‘bugbe kan nihin 

   Ibiti ero gbe nsimi

   Emi ‘ba n’iye b’adaba 

   Mba fo sinu re, mba simi.


5. Dake okan mi, ma binu 

   Akoko Oluwa l’oye

   T’emi ni lati se ‘fe Re

  Tire lati se mi l’ogo. AminEnglish »

Update Hymn