HYMN 575

H.C 355 t. Alexander’s 
New Revival Hymns 112 or
S.15 D. 7s 6s (FE 602)
"K' enyin ba le duro l’ojo ibi” - Efe. 6:131. DURO, Duro fun Jesu 

   Enyin om’ogun Kristi 

   Gbe asia re soke

   A ko gbodo fe ku

   Lat'isegun de segun

   Ni y’o to ogun Re

   Tit'a o segun gbogb'ota 

   Ti Krist y'o j’Oluwa.


2. Duro, duro fun Jesu 

   F’eti s’ohun ipe, 

   Jade lo s'oju ‘ija 

   L'oni ojo nla Re 

   Enyin akin ti nja fun 

   Larin ainiye ota 

   N‘nu ewu, e ni gboiya 

   E kojuja s’ota.


3. Duro, Duro fun Jesu 

   Duro I’agbara Re 

   Ipa enia ko to

   Ma gbekele tire

   Di ‘hamora ‘hinrere 

   Ma sona, ma gbadura 

   B’ise tab’ewu ba pe 
 
   Mase alai de ‘be.


4. Duro, Duro fun Jesu 

   lja nla ki y'o pe 

   Oni, ariwo ogun

   Ola, orin’segun

   Enit‘ o ba si segun 

   Y’o gba ade iye

   Y’o ma ba Oba Ogo 

   Joba titi lailai. Amin

English »

Update Hymn