HYMN 577

C.M.S 379, H.C 92 C.M (FE 604) 
“Awon ogun orun si nto lehin"
- Ifi 19:141. OMO Olorun nlo s’ogun 

   Lati gbade Oba

   Opagun re si nfe lele 

   Tal’ o s’om’ ogun Re.


2. Eniti O le mu ago na 

   T’O le bori’rora

   T’o le gbe agbelelbu Re 

   On ni Om’ogun Re.


3. Martyr ikini ti o ko ku 

   T’o r’orun si sile

   T’o ri Oluwa re loke 

   T'o pe, k‘o gba on la.


4. T’on ti ‘dariji l’enu 

   Ninu ‘rora iku

   O bebe f’awon t’o npa lo 

   Tani le se bi re?


5. Egbe mimo, awon wonni 

   T‘Emi Mimo ba le 

   Awon akoni mejila

   Ti ko ka iku si.


6. Nwon Faiya ran ida ota 

   Nwon ba eranko ja

   Nwon f ’orun won lele fun ’ku 

   Tani le se bi won?


7. Egbe ogun, t’agba, t’ewe 

   T’okunrin, t’obinrin 

   Nwon y’ite Olugbala ka 

   Nwon wo aso funfun.


8. Nwon de oke orun giga 

   N’nu ‘se at’iponju 

   Olorun, fun wa l’agbara 

   K’a le se bi ti won. Amin

English »

Update Hymn