HYMN 581

H.C 357 11s (FE 608) 
"So fun awon omo Isreal pe ki
nwon tesiwaju" - Eks. 14:151. E MA te siwaju, Serafu mimo 

   Gbe ‘da segun soke s’esu ati ese 

   Baba Olusegun ti segun fun wa 

   E ma beru larin ainiye ota

   K’a se fe Oluwa, b’ara igbani 

   On to gbo t’Abrahamu

   Yio gbo tiwa.


2. E ma te siwaju, Kerubu mimo 

   O di jeriko wo nipa orin won

   Lati ipa de ‘pa nwon nko ikogun 

   Tesiwaju larin ainiye egan

   K'a se 'fe Oluwa, b’ara igbani 

   On to gbo ti Mose, yio gbo tiwa.


3. Ranti agbara Re niwaju oba ni 

   Ranti isegun Re ni okun pupa 

   Owo Awosanmo li osan gangan 

   Ati owon ina Re fun won l'oru 

   K’a se fe Oluwa, b'ara igbani

   On to gbo ti Joshua, yio gbo ti wa.


4. Baba Olupese yio pese fun wa 

   Ranti ipese re ninu aginju

   Lati ‘nu apata o fun won l'omi

   O fi manna ati aparo bo won

   Kas e fe Oluwa b’ara igbani 

   On to gbo ti Daniel, yio gbo itwa.


5. E ma te siwaju, bi ‘danwo ba de 

   E sa kun f’adura, e o si bori 

   Agbara Oluwa li abo fun wa

   Ranti Sedrak, Mesaki at’Abednigo 

   K'a se fe Oluwa b‘ara igbani 

   On to gbo t‘Elijah, yio gbo tiwa.


6. Serafu t’aiye yi, eku ajodun 

   Kerubu t’aiye yi, e ku ajodun 

   Ajodun nla kan mbo ti ao se loke 

   Pelu awon Mimo lati yin Baba 

   Ka se ‘fe Oluwa, b’ara igbani 

   Metalokan Mimo yio gbo tiwa. Amin

English »

Update Hymn