HYMN 583

H.C 68 S.M (FE 609)
"E di amure nyin, ki ina nyin 
ki o si ma tan" - Luku 12:351. IRANSE Oluwa! 

   Eduro nd‘ise

   E toju oro mimo Re 

   E ma sona Re sa.


2. Jek’imole nyin tan 

   E tun fitila se

   E damure girigiri 

   Oruko Re l‘eru.


3. Sora! l’ase Jesu

   B‘a ti nso, ko jina

   B‘o ba kuku ti kan ’lekun 

   Ki e si fun logan.


4. lranse ‘re l‘emi

   Ti a ba nipo yi

   Ayo l’ on o fi r’Oluwa 

   Y’o f’ola de l’ade.


5. Kristi tikalare

   Y’o te tabili fun

   Y’o gb‘ori iranse na ga 

   Larin egbe Angel. Amin

English »

Update Hymn