HYMN 585

C.M.S 384, H.C 350 t.H.C 147.
7S (FE 611)
“Bi o se temi ati ile mi ni, Oluwa 
li a o ma sin" - Jos. 24:151. GBA aiye mi, Oluwa 

   Mo ya si mimo fun O

   Gba gbogbo akoko mi

   Ki nwon kun fun iyin Re.


2. Gba owo mi k’o si je

   Ki nma lo fun ife Re 

   Gba ese mi, k’o si je

   Ki nwon ma sare fun O.


3. Gba ohun mi, je ki nma 

   Korin f’Oba mi titi 

   Gba ete mi, jeki nwon 

   Ma jise fun O titi.


4. Gba wura, fadaka mi 

   Okan nki o da duro 

   Gba ogbon mi, k'o si lo 

   Gege bi O ba ti fe.


5. Gba ‘femi, fi seTire 

   Ki o tun je temi mo 

   Gb’okan mi Tire n’ise 

   Ma gunwa nibe titi.


6. Gba ‘feran mi, Oluwa

   Mo fi gbogbo re fun O 

   Gb'emi papa, lat’oni

   Ki n’je Tire titi lai. Amin

English »

Update Hymn