HYMN 587
S.66 P.M (FE 613)
"Oru mbo wa, nigbati enikan ki 
o le sise” - John 9:4
1.  SISE tori oru mbo! 
     Sise li owuro
     Sise nigba iri nse, 
     sise n‘nu ‘tanna 
     Sise ki osan to pon, 
     sise nigb‘orun nran 
     Sise tori oru mbo! 
     gba ‘se o pari.
2.  Sise tori oru mbo! 
     Sise losan gangan 
     F'akoko rere fun ‘se, 
     isimi daju 
     F'olukuluku igba,
     ni nkan lati pamo 
     Sise tori oru mbo! 
     ‘gba 'se o pari.
3.  Sise tori oru mbo! 
     orun fere wo na 
     Sise gbat' imole wa, 
     ojo bu Io tan
     Sise titi de opin, 
     sise titi de ale
     Sise gbat'ile ba nsu, 
     ‘gba se o pari.  Amin
English »Update Hymn